Free cookie consent management tool by TermsFeed
ISTSS Logo ISTSS Logo
 
Home > ISTSS 38th Annual Meeting > Ọgbẹ́ Ẹ̀mí Gẹ́gẹ́ Bíi Àmì Ìfinrinlẹ̀ Ìdààmù Ninu Ìsẹ̀mí Ọmọ Ènìyàn

Ọgbẹ́ Ẹ̀mí Gẹ́gẹ́ Bíi Àmì Ìfinrinlẹ̀ Ìdààmù Ninu Ìsẹ̀mí Ọmọ Ènìyàn

Ìdí ò̟ràn pàtàkì wà láti sa gbogbo ipá a wa lati gbó̟ agbó̟ye nipa àkóbá aláìĺgbé̟ tí o̟gbé̟-ẹ̀mí ń fà fún àwo̟n o̟mo̟ adáríhurun. Láti orí ìrírí o̟gbé̟-ẹ̀mí tí ó níí se pẹ̀lu  àjàkálẹ̀-àrùn un COVID-19, dé oríi o̟gbé̟-ẹ̀mí àìfúnni ni iwò̟ eni tí o níi se pẹ̀lu u ìkórira e̟lé̟yàmè̟ya pẹ̀lu  ìmúnisìn ti àtijó̟, ìgbà tí a tun ń lò ló̟wó̟ nìlò ìfojú sùnùkùn àti ìwadìí ìjìnlẹ̀  wo orísìrísìí ò̟nà tí o̟gbé̟-ẹ̀mí se di alábàkúu ẹ̀mí i wa, ara a wa àti ò̟nà tí a ń gbà á se nǹkan láwùjo̟. Bí o tilẹ̀ já sí pé PTSD ń se àgbéyẹ̀wò oníranǹran àrùn un o̟po̟lo̟ tí o jo̟mó̟ o̟gbé̟-ẹ̀mí, o jé̟ oun mímò̟ pé o̟gbé̟-ẹ̀mí a má a se àkóbá fún àbájáde oníranǹran agbo̟ngbo̟n ìlera o̟po̟lo̟ àti  ara nínu ìsẹ̀mí ẹ̀dá ènìyàn. Fún ìdí èyìí, a gbó̟dò̟ wòye si  o̟gbé̟-ẹ̀mí gé̟gé̟ bíi àmì i ìfirinlẹ̀ ìdààmú oníranǹran  ìgbésẹ̀ ajo̟mó̟lera ẹ̀mí àti  àgó̟ ara tí ó máa n farasin ko̟já a ààla ayẹ̀wò. Ìwadìí ò̟tun àti àwo̟n ìlànà ìwòsàn tí ó fi ààyè gba oníranǹran ìfàśyìn àlááfìà ẹ̀mí àti ara ĺyìn o̟gbé̟-ẹ̀mí jé̟ oun pàtàkì  tí a nílò fún ìtẹ̀síwájú u ẹ̀ka ìwadìí ìjìnlẹ̀ àti isé̟ lórí i o̟gbé̟-ẹ̀mí.

Ìpàdé àpérò o ìkejìdínlógójì o̟ló̟do̟o̟dún ISTSS yóò bojú wo onírúúrú àkóbá tí o̟gbé̟-ẹ̀mí ń fà sínú ìsẹ̀mí o̟mo̟ ènìyàn. Àpérò ti o̟dún yìì yóò se àgbéyẹ̀wò o orísìírísìí ò̟nà tí wàhálà ajo̟mó̟ o̟gbé̟- ẹ̀mí  se ń fara hàn lorí i ìlera ẹ̀mí àti ara jákèjádò oníranǹran ẹ̀dá ènìyàn àti lórí i ìsẹ̀mí ẹ̀dá.  Ní ìbámu pẹ̀lu u èróńgbà òkè yìí, a ń bèèrè fún àpilẹ̀ko̟ tí ó múnádóko lórí i orísìí ò̟nà ìwadìí o̟gbé̟-ẹ̀mí; eléyìí tí òǹkò̟wé yóò yan nànà oníranǹran ojú ò̟nà ìgbágbó̟yé e ìmò̟ ìjìnlẹ̀ ìwadìí àrùn un ajo̟mẹ̀mí. Bákan náà ẹ̀wẹ̀, àpérò yìì yóò nílò isé̟ ìwadìí tí ó kógojá lórí i oníranǹran àléébù tí o  jo̟mó̟ o̟gbé̟-ẹ̀mí. Àpérò yìì fara mó̟ àpilẹ̀ko̟ tí ó dá lórí i onírúúrú àléébù ìlera tí ipò ẹ̀mí lé̟yìn o̟gbé̟-ẹ̀mí má a ń fà, àti bí àlááfíà ara àti ẹ̀mí se ń be̟ pò̟ lé̟yìn o̟gbé̟-ẹ̀mí. Ní ìbámu pẹ̀lu u àpilẹ̀ko̟ tí ó dá lórí i ìdènà o̟gbé̟-ẹ̀mí, isé̟ ìwadìí ò̟tun nípa ìfe̟sè̟rinlè̟ o̟gbé̟-ẹ̀mí, ìtó̟jú o̟gbé̟-ẹ̀mí àti ìtó̟jú tí ó jo̟mó̟ àwo̟n àìlera tí o ń je̟yo̟ lé̟yìn ìfaragbà o̟gbé̟-ẹ̀mí gbó̟dò̟ farapé̟ kóko ìwadìí àpérò náà. Àwo̟n àfojúsùn àkójo̟ yìì ní láti sàfihàn èsì ìwadìí tí a le rí mú jáde tí a bá fi awò ńlá wo o̟gbé̟-ẹ̀mí ko̟já a PTSD; àti láti fi han aráyé bí àìfo̟wó̟ ye̟pe̟re̟ mú àwo̟n ìgbésẹ̀ àti ipa wòn yìì le kó lórí i ìlàna a alábó̟dé tí ó jo̟mó̟ ìtẹ̀síwájú àlááfìà àwo̟n ẹ̀dá tí o ń rí ìnira o̟gbé̟-ẹ̀mí.

Èróńgbà Ìké̟kò̟ó̟

  1. Sàpèjúwe bí a se lè lo ìlàna a ìwadìí ìfirinlè̟ àìlera láti ní ìmò̟ nípa ìfarahàn àìsàn inú ẹ̀mí lé̟yìn ìdààmù o̟gbé̟-ẹ̀mí.
  2. Sàfihàn orísìrísìí ò̟nà tí ìdààmù láti ipasẹ̀ o̟gbé̟-ẹ̀mí fi ń dákún àìsàn o̟po̟lo̟ àti  àìsàn ara nínú ìsẹ̀mí ẹ̀dá ènìyàn.
  3. Sàlàyé àwo̟n ìtẹ̀síwájú ìgbésẹ̀ lóríi onírúúrú ìtó̟jú tí ó jo̟mó̟ àìsàn o̟gbé̟-ẹ̀mí tí ó sàlàyé lé̟kúnré̟ré̟ nípa onírúúrú àléébù o̟gbé̟-ẹ̀mí lórí i ìlera ẹ̀dá.
A ó nífé̟ sí àpilẹ̀ko̟ tí ó jo̟mó̟-amó̟ tí kò pinsí:
  • Ìwadìí lóríi àwo̟n ìlàna fún isé̟ ìwadìí lórí àìsàn tí ó ń jẹyo̟ lé̟yìn ìdààmù o̟gbé̟-ẹ̀mí.
  • Ìwadìí oníranǹran àìlera o̟po̟lo̟ àti ara tí ó le jẹyo̟ lé̟yìn o̟gbé̟-ẹ̀mí.
  • Ìwadìí tí ó ń sàfihàn oníranǹran àárẹ̀ tí ó ń jẹyo̟ lé̟yìn o̟gbé̟-ẹ̀mí.
  • Ìwadìí tí ó se àkóónú orísìí ìpele ífó̟síwé̟wé̟ (bí apẹrẹ ajo̟mó̟ ìmò̟ abẹ̀mí, ìmò̟ ìsesí, àti ìmò̟ ìfararora) láti dèna àwo̟n okùnfa ìfarahàn àìsàn o̟po̟lo̟ àti  àìsàn ara lé̟yìn ìdààmù o̟gbé̟-ẹ̀mí.
  • Ìwadìí tí ó wòye si ìgbé ayé o̟mo̟ ènìyàn láti sàlàyé bí o̟gbé̟-ẹ̀mí se ń lapa lórí i àlááfíà ẹ̀mí àti/tàbi bí o̟gbé̟-ẹ̀mí se ń sodo sára ènìyàn láti dèna àlááfíà ara.
  • Ìwadìí lórí i àwo̟n ò̟nà ìtó̟jú ò̟tun tí ó wòye si  oníranǹran àkóbá tí o̟gbé̟-ẹ̀mí ń fà. (bí apẹrẹ isé̟ ìwadìí ò̟tun nípa ìfe̟sè̟rinlè̟ o̟gbé̟-ẹ̀mí, ìtó̟jú tí ó jo̟mó̟ àwo̟n àìlera tí o ń je̟yo̟ lé̟yìn ìfaragbà o̟gbé̟-ẹ̀mí).