Free cookie consent management tool by TermsFeed
ISTSS Logo ISTSS Logo
 

Yiyan Orukọ fun Eye Idanilola ti ISTSS Egbeewa o le metalelogun (ISTSS 2023)‎

Igbimọ Eye Idanilola ISTSS ni inu-didùn lati kede ṣiṣi yiyan awon oruko fun odun egbeewa o le metalelogun Eye Idanilola ti ISTSS (2023 ISTSS). ISTSS nfunni ni ọpọlọpọ eye idanilola lati se idanimọ ilowosi ti awọn onimo iwadi, awọn oṣiṣẹ ile-iwosan, ati awọn alagbawi si aaye eko aapon ikolu. Awujọ ISTSS naa yoo ṣe ifihan awọn to pegede fun eye idanilola ninu Ipade Ọlodọọdun ti ookandinlogoji ti ISTSS, ti yoo wa ni ojo kini si ojo kerin Oṣu kọkanla odun Egbeewa o le metalelogun (November 1 to 4, 2023), ni Los Angeles, California, Orilẹde Amẹrika.  Awọn ifisilẹ oruko fun eye idanilola yoo wa si opin ni ojo karundinlogun osu Karun odun Egbeewa o le metalelogun (May 15, 2023) ni dede agogo mejila ku iseju kan oru (11:59pm) ti akoko Imọlẹ Ila-oorun orilede Amerika.
 
Fun ẹye idanilola kọọkan, a le yan ara wa tabi ki elomiran yan wa. A le yan enikan soso fun orisirisi eye idanilola pupọ. Nigbati o ba gbero tani ki o yan fun eye idanilola wọnyi, ISTSS ṣe iwuri fun awọn ifisilẹ oruko lati ọdọ awọn olubẹwẹ lati awọn ipilẹ ti ko ni asoju to ati lati awọn orilẹ-ede ti kii se Ariwa America, ati agbegbe re. Awọn ọmọ ẹgbẹ igbimọ ti a dibo yan ko leto si awon eye idanilola wonyi.
 
Nitori awon opolopo ifisilẹ oruko fun awọn eye idanilola wọnyi, Igbimọ ko lagbara lati gbero awọn ohun elo afikun. Awọn ifisilẹ oruko ti o kọja ohun ka kikọ tabi awọn opin oju-iwe, tabi awọn ifisilẹ oruko lẹhin ọjọ yiyan ko ni ni anfani agbeyewo.

A le fi awọn ibeere tabi itọsọna wa sowo si Igbimọ Eye Idanilola ni oju ifiranse yi [email protected]